Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 28:16-21 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ètò ìwọ̀n wúrà fún tabili àkàrà ìfihàn kọ̀ọ̀kan ati ìwọ̀n fadaka fún tabili fadaka kọ̀ọ̀kan,

17. ìwọ̀n ojúlówó wúrà fún àwọn àmúga tí a fi ń mú ẹran, àwọn agbada, àwọn ife, àwọn abọ́ wúrà ati ti ìwọ̀n abọ́ fadaka kọ̀ọ̀kan,

18. ìwọ̀n pẹpẹ turari tí a fi wúrà yíyọ́ ṣe ati ohun tí ó ní lọ́kàn nípa àwọn kẹ̀kẹ́ wúrà àwọn Kerubu tí wọ́n na ìyẹ́ wọn bo Àpótí Majẹmu OLUWA.

19. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ó kọ sílẹ̀ fínnífínní gẹ́gẹ́ bí ìlànà láti ọ̀dọ̀ OLUWA nípa iṣẹ́ inú tẹmpili; ó ní gbogbo rẹ̀ ni wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà.

20. Dafidi bá sọ fún Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Múra gírí, mú ọkàn le, kí o sì ṣe bí mo ti wí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì; nítorí OLUWA Ọlọrun, àní Ọlọrun mi, wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀, títí tí iṣẹ́ ilé OLUWA yóo fi parí.

21. Gbogbo ètò iṣẹ́ ati pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ninu tẹmpili ni a ti ṣe fínnífínní. Àwọn tí wọ́n mọ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ yóo wà pẹlu rẹ, bákan náà, àwọn olórí ati gbogbo eniyan Israẹli yóo wà lábẹ́ àṣẹ rẹ.”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 28