Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 27:24-34 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi.

25. Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́.

26. Esiri, ọmọ Kelubu, ni alabojuto fún gbogbo iṣẹ́ oko dídá.

27. Ṣimei, ará Rama, ni ó wà fún àwọn ọgbà àjàrà. Sabidi, ará Ṣifimu, ni ó wà fún ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí.

28. Baali Hanani, ará Gederi, ni ó wà fún àwọn ọgbà olifi ati ti igi sikamore. Joaṣi ni ó wà fún ibi tí wọ́n ń kó òróró olifi pamọ́ sí.

29. Ṣitirai, ará Ṣaroni, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní Ṣaroni. Ṣafati, ọmọ Adila, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní àwọn àfonífojì.

30. Obili, ará Iṣmaeli, ni ó wà fún àwọn ràkúnmí. Jedeaya, ará Meronoti, ni ó wà fún àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jasisi, ará Hagiri, sì jẹ́ alabojuto àwọn agbo aguntan.

31. Gbogbo wọn jẹ́ alabojuto àwọn ohun ìní Dafidi ọba.

32. Jonatani, arakunrin baba Dafidi ọba, ni olùdámọ̀ràn nítorí pé ó ní òye, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé. Òun ati Jehieli, ọmọ Hakimoni, ní ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ ọba.

33. Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn fún ọba, Huṣai ará Ariki sì ni ọ̀rẹ́ ọba.

34. Lẹ́yìn ikú Ahitofeli, Jehoiada, ọmọ Bẹnaya ati Abiatari di olùdámọ̀ràn ọba. Joabu sì jẹ́ balogun ọba.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 27