Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 26:29-32 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Ninu ìdílé Iṣari, Kenanaya ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n yàn ní alákòóso ati onídàájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli.

30. Ninu ìdílé Heburoni, Haṣabaya ati ẹẹdẹgbẹsan (1,700) àwọn arakunrin rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alágbára ni wọ́n ń bojútó àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ OLUWA ati iṣẹ́ ọba,

31. Ninu ìdílé Heburoni, Jerija ni baba ńlá gbogbo wọn. (Ní ogoji ọdún tí Dafidi dé orí oyè, wọ́n ṣe ìwádìí nípa ìran Heburoni, wọ́n sì rí àwọn ọkunrin tí wọ́n lágbára ninu ìran wọn ní Jaseri ní agbègbè Gileadi).

32. Dafidi ọba, yan òun ati àwọn arakunrin rẹ̀, tí gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaa ó lé ẹẹdẹgbẹrin (2,700) alágbára, láti jẹ́ alámòójútó àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase nípa gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun ati àwọn nǹkan tó jẹ́ ti ọba.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 26