Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 24:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí a ṣe pín àwọn ọmọ Aaroni nìyí: Aaroni ní ọmọkunrin mẹrin: Nadabu, Abihu, Eleasari ati Itamari.

2. Nadabu ati Abihu kú ṣáájú baba wọn láì bí ọmọ kankan. Nítorí náà, Eleasari, ati Itamari di alufaa.

3. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari ati Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi pín àwọn ọmọ Aaroni sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn.

4. Àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé pọ̀ ninu àwọn ọmọ Eleasari ju ti Itamari lọ, nítorí náà, wọ́n pín àwọn ọmọ Eleasari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹrindinlogun, wọ́n sì pín àwọn ọmọ Itamari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹjọ. Bí wọ́n ṣe pín wọn kò sì fì sí ibìkan nítorí pé

Ka pipe ipin Kronika Kinni 24