Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 23:8-26 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àwọn ọmọ Ladani jẹ́ mẹta: Jeieli tí ó jẹ́ olórí, Setamu ati Joẹli.

9. Àwọn ọmọ Ṣimei ni Ṣelomoti, Hasieli, ati Harani; àwọn ni wọ́n jẹ́ olórí ìdílé Ladani.

10. Àwọn ọmọ Ṣimei jẹ́ mẹrin: Jahati, Sina, Jeuṣi, ati Beraya.

11. Jahati ni ó jẹ́ olórí, Sisa ni igbákejì rẹ̀, ṣugbọn Jeuṣi ati Beraya kò bí ọmọ pupọ, nítorí náà ni wọ́n fi kà wọ́n sí ìdílé kan ninu ọ̀kan ninu àwọn àkọsílẹ̀.

12. Àwọn ọmọ Kohati jẹ́ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni, ati Usieli,

13. Àwọn ọmọ Amramu ni Aaroni ati Mose. Aaroni ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, pé kí òun ati àwọn ìran rẹ̀ títí lae máa sun turari níwájú OLUWA, kí wọ́n máa darí ìsìn OLUWA, kí wọ́n sì máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ rẹ̀ títí lae.

14. A ka àwọn ọmọ Mose, iranṣẹ Ọlọrun, pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà Lefi.

15. Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri.

16. Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu.

17. Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀.

18. Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀.

19. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu.

20. Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya.

21. Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi,

22. Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn.

23. Àwọn ọmọ Muṣi jẹ́ mẹta: Mahili, Ederi ati Jeremotu.

24. Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.

25. Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae.

26. Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 23