Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 23:24-32 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.

25. Dafidi ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi, yóo sì máa gbé Jerusalẹmu títí lae.

26. Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní máa ru Àgọ́ Àjọ ati àwọn ohun èlò tí wọn ń lò ninu rẹ̀ káàkiri mọ́.”

27. Gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi ti ṣe, iye àwọn ọmọ Lefi láti ogún ọdún sókè nìyí:

28. Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA.

29. Àwọn ni wọ́n tún ń ṣe ètò ṣíṣe burẹdi ìfihàn, ìyẹ̀fun fún ẹbọ ohun jíjẹ, àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ninu, àkàrà díndín fún ẹbọ, ẹbọ tí a po òróró mọ́, ati pípèsè àwọn oríṣìíríṣìí ìwọ̀n.

30. Wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA ní àràárọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́,

31. ati nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí OLUWA ní ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ oṣù titun, tabi ọjọ́ àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn tí a yàn láti máa kọrin níwájú OLUWA nígbà gbogbo.

32. Bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa bojútó Àgọ́ Àjọ ati ibi mímọ́, tí wọn yóo sì máa ran àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn lọ́wọ́, níbi iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 23