Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 23:14-24 BIBELI MIMỌ (BM)

14. A ka àwọn ọmọ Mose, iranṣẹ Ọlọrun, pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà Lefi.

15. Mose bí ọmọkunrin meji: Geriṣomu ati Elieseri.

16. Àwọn ọmọ Geriṣomu ni: Ṣebueli, olórí ìdílé Geriṣomu.

17. Elieseri bí ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Rehabaya, olórí ìdílé rẹ̀, kò sì bí ọmọ mìíràn mọ́, ṣugbọn àwọn ọmọ Rehabaya pọ̀.

18. Iṣari bí ọmọkunrin kan, Ṣelomiti, tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀.

19. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Jeraya, tí ó jẹ́ olórí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Amaraya, Jahasieli, Jekameamu.

20. Usieli bí ọmọ meji: Mika, tí ó jẹ́ olórí, ati Iṣaya.

21. Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Mahili bí ọmọkunrin meji: Eleasari ati Kiṣi,

22. Ṣugbọn Eleasari kú láì ní ọmọkunrin kankan; kìkì ọmọbinrin ni ó bí. Àwọn ọmọbinrin rẹ̀ bá fẹ́ àwọn ọmọ Kiṣi, àbúrò baba wọn.

23. Àwọn ọmọ Muṣi jẹ́ mẹta: Mahili, Ederi ati Jeremotu.

24. Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 23