Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 22:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà Dafidi pàṣẹ pé, “Ibí yìí ni ilé OLUWA Ọlọrun, ati pẹpẹ ẹbọ sísun yóo wà fún Israẹli.”

2. Dafidi pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli péjọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn ṣiṣẹ́, ara wọn ni wọ́n gbẹ́ òkúta fún kíkọ́ tẹmpili.

3. Ó kó ọpọlọpọ irin jọ, tí wọn óo fi rọ ìṣó, tí wọn yóo fi kan àwọn ìlẹ̀kùn ati ìdè, ó kó idẹ jọ lọpọlọpọ pẹlu, ju ohun tí ẹnikẹ́ni lè wọ̀n lọ,

4. ati ọpọlọpọ igi kedari. Ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eniyan kò le kà wọ́n, nítorí pé ọpọlọpọ igi kedari ni àwọn ará Sidoni ati Tire kó wá fún Dafidi.

5. Nítorí pe Dafidi ní, “Tẹmpili tí a óo kọ́ fún OLUWA gbọdọ̀ dára tóbẹ́ẹ̀ tí òkìkí rẹ̀ yóo kàn ká gbogbo ayé; bẹ́ẹ̀ sì ni Solomoni, ọmọ mi, tí yóo kọ́ ilé náà kéré, kò sì tíì ní ìrírí pupọ. Nítorí náà, n óo tọ́jú àwọn ohun èlò sílẹ̀ fún un.” Dafidi bá tọ́jú àwọn nǹkan tí wọn yóo lò sílẹ̀ lọpọlọpọ kí ó tó kú.

6. Dafidi bá pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó pàṣẹ fún un pé kí ó kọ́ ilé kan fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 22