Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 2:21-38 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nígbà tí Hesironi di ẹni ọgọta ọdún, ó fẹ́ ọmọbinrin Makiri, baba Gileadi. Ọmọbinrin yìí sì bí ọmọkunrin kan fún un tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Segubu.

22. Segubu ni ó bí Jairi, tí ó jọba lórí ìlú ńláńlá mẹtalelogun ní ilẹ̀ Gileadi.

23. Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi.

24. Lẹ́yìn ìgbà tí Hesironi kú, Kalebu ṣú Efurata, iyawo baba rẹ̀ lópó, ó sì bí Aṣuri, tíí ṣe baba Tekoa.

25. Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija.

26. Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu.

27. Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri.

28. Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri.

29. Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un.

30. Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú.

31. Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai.

32. Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú.

33. Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli.

34. Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha.

35. Ṣeṣani fi ọmọ rẹ̀ obinrin fún Jariha, ẹrú rẹ̀, ó sì bí Atai fún ẹrú náà.

36. Atai ni baba Natani, Natani sì ni baba Sabadi.

37. Sabadi bí Efiali, Efiali sì bí Obedi.

38. Obedi ni baba Jehu, Jehu sì ni baba Asaraya.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 2