Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 17:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kan ní àkókò tí Dafidi ọba ń gbe ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani, wolii, pé, “Wò ó, èmi ń gbé ilé tí a fi igi kedari kọ́, ṣugbọn Àpótí Majẹmu OLUWA wà ninu àgọ́.”

2. Natani bá dá a lóhùn pé, “Ṣe gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ, nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu rẹ.”

3. Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an, Ọlọrun sọ fún Natani pé,

4. “Lọ sọ fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, èmi ‘OLUWA sọ pé kì í ṣe òun ni óo kọ́ ilé tí n óo máa gbé fún mi.

5. Nítorí pé n kò tíì gbé inú ilé kankan láti ìgbà tí mo ti kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò lóko ẹrú títí di òní. Inú àgọ́ kan ni mo ti ń dé inú àgọ́ mìíràn, tí mo sì ń lọ láti ibìkan dé ibòmíràn.

6. Sọ pé, mo ní ninu gbogbo ibi tí mo ti ń bá àwọn ọmọ Israẹli lọ káàkiri, ǹjẹ́ mo tíì yanu bèèrè lọ́wọ́ onídàájọ́ kankan, lára àwọn tí mo pàṣẹ fún láti máa darí àwọn eniyan mi, pé kí wọ́n kọ́ ilé kedari fún mi?’

7. “Nítorí náà, sọ fún un pé, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ‘mo mú un wá láti inú pápá, níbi tí ó ti ń da ẹran, pé kí ó wá jọba lórí, àwọn eniyan mi, Israẹli.

8. Mo sì ń wà pẹlu rẹ̀ ní gbogbo ibi tí ó ń lọ, mo sì ti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run níwájú rẹ̀, n óo sì gbé orúkọ rẹ̀ ga bí orúkọ àwọn eniyan ńlá ayé.

9. N óo yan ibìkan fún Israẹli, àwọn eniyan mi, n óo fìdí wọn múlẹ̀, wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn, ẹnikẹ́ni kò ní yọ wọ́n lẹ́nu mọ́, àwọn ìkà kò tún ní ṣe wọ́n lófò mọ́ bíi ti àtijọ́,

10. nígbà tí mo ti yan àwọn adájọ́ láti darí Israẹli, àwọn eniyan mi. N óo tẹ orí àwọn ọ̀tá wọn ba. Bákan náà, èmi OLUWA ṣe ìlérí pe n óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀.

11. Nígbà tí ọjọ́ bá pé tí ó bá kú, tí a sin ín pẹlu àwọn baba rẹ̀, n óo gbé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ dìde, àní ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin rẹ̀, n óo sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.

12. Yóo kọ́ ilé kan fún mi, n óo jẹ́ kí atọmọdọmọ rẹ̀ wà lórí ìtẹ́ títí lae.

13. N óo jẹ́ baba fún un, yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi. N kò ní yẹ ìfẹ́ ńlá mi tí mo ní sí i, bí mo ti yẹ ti Saulu, tí ó ṣáájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 17