Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 16:27-40 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ògo ati agbára yí i ká,ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀.

28. Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé,ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́!

29. Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un,ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀!Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́,

30. ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé,ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae.

31. Kí inú ọ̀run kí ó dùn,kí ayé kí ó yọ̀,kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!”

32. Kí òkun ati ohun gbogbo tó wà ninu rẹ̀ hó yèè,kí pápá oko búsáyọ̀, ati gbogbo ẹ̀dá tó wà ninu rẹ̀.

33. Àwọn igi igbó yóo kọrin ayọ̀níwájú OLUWA, nítorí ó wá láti ṣe ìdájọ́ ayé.

34. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun,ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae!

35. Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa,kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ,kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.

36. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli,lae ati laelae!”Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.

37. Dafidi fi Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí iwájú Àpótí Majẹmu OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn níbẹ̀ lojoojumọ,

38. pẹlu Obedi Edomu ati àwọn arakunrin rẹ̀ mejidinlaadọrin; ó sì fi Obedi Edomu, ọmọ Jedutuni ati Hosa ṣe aṣọ́nà.

39. Ó fi Sadoku, alufaa ati àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ibi Àgọ́ OLUWA ní ibi pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Gibeoni,

40. láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ ẹbọ sísun, ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́, bí wọ́n ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 16