Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 14:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Hiramu, ọba Tire kó àwọn òṣìṣẹ́ ranṣẹ sí Dafidi, pẹlu igi kedari ati àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti bá a kọ́ ilé rẹ̀.

2. Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀.

3. Dafidi tún fẹ́ àwọn iyawo mìíràn ní Jerusalẹmu, ó sì bí àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin sí i.

4. Àwọn tí ó bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua, Ṣobabu, Natani, ati Solomoni;

5. Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti;

6. Noga, Nefegi, ati Jafia;

7. Eliṣama, Beeliada, ati Elifeleti.

8. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi òróró yan Dafidi lọ́ba lórí Israẹli, gbogbo wọn wá gbógun ti Dafidi. Nígbà tí Dafidi gbọ́, òun náà múra láti lọ gbógun tì wọ́n.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 14