Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 12:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Joela, ati Sebadaya, àwọn ọmọ Jehoramu, ará Gedori.

8. Àwọn ọkunrin tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Gadi láti darapọ̀ mọ́ Dafidi, ní ibi ààbò tí ó wà ninu aṣálẹ̀ nìwọ̀nyí; akọni ati ògbólógbòó jagunjagun ni wọ́n, wọ́n já fáfá ninu lílo apata ati ọ̀kọ̀, ojú wọn dàbí ti kinniun, ẹsẹ̀ wọn sì yá nílẹ̀ bíi ti ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín lórí òkè.

9. Orúkọ wọn, ati bí wọ́n ṣe tẹ̀léra nìyí: Eseri ni olórí wọn, lẹ́yìn náà ni Ọbadaya, Eliabu;

10. Miṣimana, Jeremaya,

11. Atai, Elieli,

12. Johanani, Elisabadi,

13. Jeremaya, ati Makibanai.

14. Àwọn ọmọ ẹ̀yà Gadi wọnyi ni olórí ogun, àwọn kan jẹ́ olórí ọgọrun-un ọmọ ogun, àwọn kan sì jẹ́ olórí ẹgbẹrun, olukuluku gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ akikanju sí.

15. Àwọn ni wọ́n la odò Jọdani kọjá ninu oṣù kinni, ní àkókò ìgbà tí ó kún bo bèbè rẹ̀, wọ́n sì ṣẹgun gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, ní apá ìhà ìlà oòrùn ati apá ìwọ̀ oòrùn.

16. Àwọn kan láti inú ẹ̀yà Juda ati ti ẹ̀yà Bẹnjamini wá sọ́dọ̀ Dafidi níbi ààbò.

17. Dafidi lọ pàdé wọn, ó ní, “Tí ẹ bá wá láti darapọ̀ mọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, ati láti ràn mí lọ́wọ́, inú mi dùn sí yín; ṣugbọn bí ẹ bá wá ṣe amí fún àwọn ọ̀tá mi, nígbà tí ó ti jẹ́ pé n kò ní ẹ̀bi, Ọlọrun àwọn baba wa rí yín, yóo sì jẹ yín níyà.”

Ka pipe ipin Kronika Kinni 12