Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 12:24-40 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Láti inú ẹ̀yà Juda, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó dín igba (6,800) wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀.

25. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, ẹẹdẹgbaarin ó lé ọgọrun-un (7,100), àwọn akọni jagunjagun ni wọ́n wá.

26. Láti inú ẹ̀yà Lefi, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó dín irinwo (4,600);

27. Jehoiada, olóyè, wá láti inú ìran Aaroni pẹlu ẹgbaaji ó dín ọọdunrun (3,700) ọmọ ogun

28. Sadoku ọdọmọkunrin akikanju jagunjagun wá, pẹlu ọ̀gágun mejilelogun ninu àwọn ará ilé baba rẹ̀.

29. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà pẹlu Saulu, àwọn tí wọ́n wá jẹ́ ẹẹdẹgbaaji (3,000). Tẹ́lẹ̀ rí, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí ìdílé Saulu.

30. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹrin (20,800) akikanju ati alágbára, tí wọ́n jẹ́ olókìkí ninu ìdílé wọn ni wọ́n wá.

31. Láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase, ẹgbaasan-an (18,000) wá; yíyàn ni wọ́n yàn wọ́n láti lọ fi Dafidi jọba.

32. Láti inú ẹ̀yà Isakari, àwọn igba (200) olórí ni wọ́n wá, àwọn tí wọ́n mọ ohun tí ó bá ìgbà mu, ati ohun tí ó yẹ kí Israẹli ṣe; wọ́n wá pẹlu àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ wọn.

33. Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaarun (50,000) àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n gbóyà, tí wọ́n mọ̀ nípa ogun jíjà, tí wọ́n sì ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹlu ọkàn kan.

34. Láti inú ẹ̀yà Nafutali, ẹgbẹrun (1,000) ọ̀gágun wá, ọ̀kẹ́ meji ó dín ẹẹdẹgbaaji (37,000) ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu wọn; gbogbo wọn ní apata ati ọ̀kọ̀.

35. Láti inú ẹ̀yà Dani, ẹgbaa mẹrinla ó lé ẹgbẹta ọkunrin (28,600) tí wọ́n dira ogun ni wọ́n wá.

36. Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti dira ogun.

37. Láti inú àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ẹ̀yà Reubẹni, ti Gadi, ati ìdajì ti Manase, ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ọmọ ogun tí wọ́n ní gbogbo ihamọra ogun ni wọ́n wá.

38. Gbogbo wọn ni wọ́n ti dira ogun, tí wọ́n wá sí Heburoni pẹlu ìpinnu láti fi Dafidi jọba lórí Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù náà sì pinnu bákan náà.

39. Wọ́n wà níbẹ̀ pẹlu Dafidi fún ọjọ́ mẹta, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, nítorí àwọn arakunrin wọn ti pèsè oúnjẹ sílẹ̀ dè wọ́n.

40. Bákan náà ni gbogbo àwọn aládùúgbò wọn láti ọ̀nà jíjìn bí ẹ̀yà Isakari ati ti Sebuluni ati Nafutali di oúnjẹ ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí, ati ìbakasíẹ, ati akọ mààlúù wá fún wọn. Wọ́n kó ọpọlọpọ oúnjẹ, àkàrà dídùn tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣe, ìdì èso resini, waini, ati òróró, pẹlu akọ mààlúù ati aguntan, nítorí pé ayọ̀ kún gbogbo orílẹ̀-èdè Israẹli.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 12