19. Eberi bí ọmọkunrin meji: Ekinni ń jẹ́ Pelegi, (nítorí pé ní àkókò tirẹ̀ ni àwọn eniyan ayé pín sí meji); ọmọ Eberi keji sì ń jẹ́ Jokitani,
20. Jokitani ni ó bí Alimodadi, Ṣelefu, Hasarimafeti, ati Jera;
21. Hadoramu, Usali, ati Dikila;
22. Ebali, Abimaeli, ati Ṣeba,
23. Ofiri, Hafila ati Jobabu; Àwọn ni àwọn ọmọ Jokitani.
24. Arọmọdọmọ Ṣemu títí fi dé orí Abramu nìyí: Ṣemu, Apakiṣadi, Ṣela;
25. Eberi, Pelegi, Reu;
26. Serugi, Nahori, Tẹra;
27. Abramu, tí a tún ń pè ní Abrahamu.
28. Àwọn ọmọ Abrahamu ni Isaaki ati Iṣimaeli.
29. Àkọsílẹ̀ ìran wọn nìyí: Nebaiotu ni àkọ́bí Iṣimaeli, lẹ́yìn náà ni ó bí Kedari, Adibeeli, ati Mibisamu;
30. Miṣima, Duma ati Masa; Hadadi ati Tema;
31. Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema.
32. Abrahamu ní obinrin kan tí ń jẹ́ Ketura. Ó bí àwọn ọmọ mẹfa wọnyi fún Abrahamu: Simirani, Jokiṣani ati Medani; Midiani, Iṣibaki ati Ṣua. Àwọn ọmọ ti Jokiṣani ni: Ṣeba ati Dedani.
33. Àwọn ọmọ marun-un tí Midiani bí ni Efa, Eferi ati Hanoku, Abida ati Elidaa. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Ketura.