Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 9:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ó fún ọba ní àwọn ẹ̀bùn wọnyi tí ó mú wá: ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn ati ohun ọ̀ṣọ́ òkúta olówó iyebíye. Kò tún sí irú turari tí ọbabinrin yìí mú wá fún Solomoni ọba mọ́.

10. Àwọn iranṣẹ Huramu ati àwọn iranṣẹ Solomoni tí wọ́n mú wúrà wá láti Ofiri, tún mú igi aligumu ati àwọn òkúta olówó iyebíye wá pẹlu.

11. Igi aligumu yìí ni ọba fi ṣe àtẹ̀gùn láti máa gòkè ati láti máa sọ̀kalẹ̀ ninu tẹmpili OLUWA ati ninu ààfin ọba. Ó tún fi ṣe dùùrù ati hapu fún àwọn akọrin. Kò sí irú wọn rí ní gbogbo ilẹ̀ Juda.

12. Solomoni ọba fún ọbabinrin náà ní gbogbo ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ẹ̀bùn tí ó fún un ju èyí tí òun alára mú wá lọ. Lẹ́yìn náà ọbabinrin náà pada lọ sí ìlú rẹ̀.

13. Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń rí ní ọdọọdún jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó lé mẹfa (666) talẹnti (kilogiramu 23,000),

14. láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ati àwọn ọlọ́jà ń mú wá. Àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina àwọn agbègbè ìjọba rẹ̀ náà a máa mú wúrà ati fadaka wá fún un.

15. Solomoni fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe igba (200) apata ńláńlá. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ṣekeli.

16. Ó tún fi wúrà tí a fi òòlù lù ṣe ọọdunrun (300) apata kéékèèké. Ìwọ̀n wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọọdunrun (300) ṣekeli. Ọba kó wọn sí ààfin Igbó Lẹbanoni.

17. Ọba fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ ojúlówó wúrà bò ó.

18. Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn kan tí ó ní ìṣísẹ̀ mẹfa ati àpótí ìtìsẹ̀ kan tí a fi wúrà ṣe, tí a kàn mọ́ ìtẹ́. Igbọwọle wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìtẹ́ náà, tí ère kinniun meji wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn.

19. Wọ́n ṣe ère kinniun mejila sí ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀gùn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Kò sí irú rẹ̀ rí ní ìjọba kankan.

20. Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife Solomoni, ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Igbó Lẹbanoni. Fadaka kò jámọ́ nǹkankan ní àkókò ìjọba Solomoni.

21. Nítorí pé, ọba ní àwọn ọkọ̀ ojú omi tí àwọn iranṣẹ Huramu máa ń gbé lọ sí Taṣiṣi. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹta ni àwọn ọkọ̀ náà máa ń dé; wọn á máa kó wúrà, fadaka, eyín erin, ati oríṣìíríṣìí àwọn ọ̀bọ ati ẹyẹ ọ̀kín wá sílé.

Ka pipe ipin Kronika Keji 9