Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 9:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ọbabinrin ìlú Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti wá dán an wò pẹlu àwọn ìbéèrè tó le. Ó wá ninu ọlá ńlá rẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni wọ́n tẹ̀lé e lẹ́yìn, pẹlu àwọn ràkúnmí tí wọ́n ru oríṣìírìṣìí turari olóòórùn dídùn, ati ọpọlọpọ wúrà ati òkúta olówó iyebíye. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un.

2. Solomoni dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ẹyọ kan tí ó rú Solomoni lójú, tí kò dáhùn pẹlu àlàyé.

3. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí ọgbọ́n Solomoni ti jinlẹ̀ tó, ati ààfin tí ó kọ́,

4. oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀ ati bí àwọn ìjòyè rẹ̀ ti jókòó, àwọn iranṣẹ rẹ̀, ìwọṣọ ati ìṣesí wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ní ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ.

5. Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Kò sí irọ́ ninu gbogbo ohun tí mo ti gbọ́ nípa rẹ ati nípa ọgbọ́n rẹ.

6. N kò gba ohun tí wọ́n sọ fún mi gbọ́ títí tí mo fi dé ìhín, tí èmi gan-an sì fi ojú ara mi rí i. Ohun tí wọ́n sọ fún mi kò tó ìdajì ọgbọ́n rẹ, ohun tí mo rí yìí pọ̀ ju ohun tí wọ́n sọ fún mi lọ.

7. Àwọn iyawo rẹ ṣoríire. Àwọn òṣìṣẹ́ rẹ tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ náà ṣoríire.

8. Ògo ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó gbé ọ gorí oyè láti jọba ní orúkọ rẹ̀. Ó ní ìfẹ́ sí Israẹli, ó fẹ́ fi ìdí wọn múlẹ̀ títí lae; nítorí náà, ó fi ọ́ jọba lórí wọn, láti máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo.”

Ka pipe ipin Kronika Keji 9