Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 8:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ilẹ̀ náà lára àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, tí wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli,

8. gbogbo ìran àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun, ni Solomoni ń fi tipátipá kó ṣiṣẹ́ títí di òní olónìí.

9. Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

10. Àwọn olórí lára àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni jẹ́ igba ati aadọta (250), àwọn ni wọ́n ń ṣe àkóso àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́.

11. Solomoni mú iyawo rẹ̀, ọmọ Farao kúrò ní ìlú Dafidi, lọ sí ibi tí ó kọ́ fún un. Ó ní, “Iyawo mi kò gbọdọ̀ máa gbé ààfin Dafidi, ọba Israẹli; nítorí pé ibikíbi tí àpótí OLUWA bá ti wọ̀, ó ti di ibi mímọ́.”

12. Solomoni rú ẹbọ sísun sí OLUWA lórí pẹpẹ OLUWA tí ó kọ́ siwaju yàrá àbáwọlé ní tẹmpili.

13. Ó ń rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Mose ti fi lélẹ̀, lojoojumọ, ati ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun ati àwọn àjọ̀dún mẹta pataki tí wọ́n gbọdọ̀ ṣe lọdọọdun: àjọ àìwúkàrà, àjọ ìkórè ati àjọ ìpàgọ́.

Ka pipe ipin Kronika Keji 8