Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 8:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó gba Solomoni ní ogún ọdún láti kọ́ tẹmpili OLUWA ati ààfin tirẹ̀.

2. Lẹ́yìn náà, ó tún àwọn ìlú tí Huramu ọba, fún un kọ́, ó sì fi àwọn ọmọ Israẹli sibẹ.

3. Ó lọ gbógun ti ìlú Hamati ati Soba, ó sì ṣẹgun wọn.

4. Ó kọ́ ìlú Tadimori ní aṣálẹ̀, ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra jọ sí ní Hamati.

5. Ó kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati Beti Horoni ti ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìlú olódi, wọ́n ní ìlẹ̀kùn ati ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn,

6. bẹ́ẹ̀ sì ni ìlú Baalati ati gbogbo ìlú tí wọn ń kó ìṣúra pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ wà, ati ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin, ati gbogbo ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ati ní Lẹbanoni, ati ní gbogbo ibi tí ìjọba rẹ̀ dé.

7. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ilẹ̀ náà lára àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, tí wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli,

8. gbogbo ìran àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun, ni Solomoni ń fi tipátipá kó ṣiṣẹ́ títí di òní olónìí.

9. Ṣugbọn kò fi ipá kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bí ẹrú, ṣugbọn ó ń lò wọ́n bíi jagunjagun, òṣìṣẹ́ ìjọba, balogun kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

10. Àwọn olórí lára àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni jẹ́ igba ati aadọta (250), àwọn ni wọ́n ń ṣe àkóso àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́.

Ka pipe ipin Kronika Keji 8