Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 7:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Solomoni parí adura rẹ̀, iná kan ṣẹ́ láti ọ̀run, ó jó gbogbo ẹbọ sísun ati ọrẹ, ògo OLUWA sì kún inú tẹmpili.

2. Àwọn alufaa kò sì lè wọ inú tẹmpili lọ mọ́ nítorí ògo OLUWA ti kún ibẹ̀.

3. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí i bí iná ati ògo OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí tẹmpili, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun, wọ́n fi ọpẹ́ fún un, “Nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé àánú rẹ̀ wà títí lae.”

4. Lẹ́yìn náà, ọba ati gbogbo àwọn eniyan rúbọ sí OLUWA.

5. Solomoni ọba fi ẹgbaa mọkanla (22,000) mààlúù ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rúbọ. Bẹ́ẹ̀ ni ọba ati gbogbo àwọn eniyan náà ṣe ya ilé Ọlọrun sí mímọ́.

6. Àwọn alufaa dúró ní ipò wọn, àwọn ọmọ Lefi náà dúró láti kọrin sí OLUWA pẹlu ohun èlò orin tí Dafidi ṣe ati ìlànà tí ó fi lélẹ̀ láti máa fi kọrin ọpẹ́ sí OLUWA pé, “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ wà títí lae;” ní gbogbo ìgbà tí Dafidi bá lò wọ́n láti kọrin ìyìn. Àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè gbogbo eniyan yóo sì dìde dúró.

7. Solomoni ya gbọ̀ngàn ààrin tí ó wà níwájú ilé OLUWA sí mímọ́, nítorí pé ibẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun tí ó sì sun ọ̀rá ẹran fún ẹbọ alaafia, nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó ṣe kò lè gba gbogbo ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ọ̀rá.

8. Solomoni ṣe àjọyọ̀ yìí fún ọjọ́ meje gbáko, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wà pẹlu rẹ̀, eniyan pọ̀ lọ bí eṣú, láti ẹnu bodè Hamati títí dé odò Ijipti.

9. Wọ́n fi ọjọ́ meje ṣe ìyàsímímọ́ pẹpẹ, wọ́n sì fi ọjọ́ meje ṣe àjọyọ̀. Ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n pe àpéjọ mímọ́.

Ka pipe ipin Kronika Keji 7