Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 6:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Solomoni ọba ní,“OLUWA, o ti sọ pé o óo máa gbé inú òkùnkùn biribiri.

2. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti kọ́ ilé kan tí ó lógo fún ọ,ibi tí o óo máa gbé títí lae.”

3. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli wà níbẹ̀, ọba bá yíjú pada sí wọn, ó sì gbadura fún wọn.

4. Lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ohun gbogbo tí ó wí fún Dafidi, baba mi, ṣẹ fúnrarẹ̀, nítorí ó wí pé,

5. ‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi.

6. Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ”

Ka pipe ipin Kronika Keji 6