Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 35:19-27 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Josaya ni wọ́n ṣe Àjọ Ìrékọjá yìí.

20. Nígbà tí ó yá lẹ́yìn tí Josaya ti ṣe ètò inú tẹmpili tán, Neko, ọba Ijipti wá jagun ní Kakemiṣi, ní odò Yufurate. Josaya sì digun lọ bá a jà.

21. Neko rán ikọ̀ sí Josaya pé, “Kí ló lè fa ìjà láàrin wa, ìwọ ọba Juda? Ìwọ kọ́ ni mo wá bá jà lákòókò yìí, orílẹ̀-èdè tí èmi pẹlu rẹ̀ ní ìjà ni mo wá bá jà. Ọlọrun ni ó sì sọ fún mi pé kí n má jáfara, má ṣe dojú ìjà kọ Ọlọrun, nítorí pé ó wà pẹlu mi; kí ó má ba à pa ọ́ run.”

22. Ṣugbọn Josaya ṣe oríkunkun, ó paradà kí wọ́n má baà dá a mọ̀, ó lọ bá a jà. Kò fetí sí ọ̀rọ̀ Neko, tí Ọlọrun sọ, ó lọ bá Neko jà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.

23. Àwọn tafàtafà ta Josaya ọba ní ọfà, ó bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé mi kúrò lójú ogun, nítorí mo ti fara gbọgbẹ́, ọgbẹ́ náà sì pọ̀.”

24. Nítorí náà, wọ́n gbé e kúrò ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà tẹ́lẹ̀ sinu òmíràn, wọ́n sì gbé e lọ sí Jerusalẹmu. Ó kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalẹmu ṣe ọ̀fọ̀ rẹ̀.

25. Wolii Jeremaya kọ orin arò fún Josaya ọba. Ó ti di àṣà ní Israẹli fún àwọn akọrin, lọkunrin ati lobinrin láti máa mẹ́nu ba Josaya nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ń kọrin arò.

26. Àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ati iṣẹ́ rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin OLUWA,

27. gbogbo ohun tí ó ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda.

Ka pipe ipin Kronika Keji 35