Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 33:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Bí àwọn ọmọ Israẹli bá pa òfin mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati ìdájọ́ mi tí mo fún wọn láti ọwọ́ Mose, n kò ní ṣí wọn nídìí mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo ti yàn fún àwọn baba wọn.”

9. Manase ṣi àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu lọ́nà, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe burúkú ju àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fún Israẹli lọ.

10. OLUWA kìlọ̀ fún Manase ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.

11. Nítorí náà, OLUWA mú kí ọ̀gágun ilẹ̀ Asiria wá ṣẹgun Juda, wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà de Manase, wọ́n fi ìwọ̀ mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Babiloni.

12. Nígbà tí ó wà ninu ìpọ́njú ó wá ojurere OLUWA Ọlọrun, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ patapata níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀.

13. Ó gbadura sí OLUWA, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, ó sì mú un pada wá sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ó wá mọ̀ nígbà náà pé OLUWA ni Ọlọrun.

Ka pipe ipin Kronika Keji 33