Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 33:2-5 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA. Gbogbo nǹkan ẹ̀gbin tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli máa ń ṣe ni òun náà ṣe.

3. Gbogbo ibi ìrúbọ tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ó tún kọ́. Ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó sì ri àwọn òpó fún Aṣera. Ó ń bọ àwọn ìràwọ̀, ó sì ń sìn wọ́n.

4. Ó tẹ́ pẹpẹ oriṣa sinu ilé OLUWA, ilé tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ pé, “Ní Jerusalẹmu ni ibi ìjọ́sìn tí orúkọ mi yóo wà, tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae.”

5. Ó tẹ́ pẹpẹ sinu gbọ̀ngàn meji tí ó wà ninu tẹmpili, wọ́n sì ń bọ àwọn ìràwọ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà lójú ọ̀run níbẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 33