Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 33:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta.

2. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA. Gbogbo nǹkan ẹ̀gbin tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli máa ń ṣe ni òun náà ṣe.

3. Gbogbo ibi ìrúbọ tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ó tún kọ́. Ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó sì ri àwọn òpó fún Aṣera. Ó ń bọ àwọn ìràwọ̀, ó sì ń sìn wọ́n.

Ka pipe ipin Kronika Keji 33