Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 32:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan tí Hesekaya ṣe, tí ó sin OLUWA pẹlu òtítọ́, Senakeribu ọba Asiria wá gbógun ti Juda. Ó dó ti àwọn ìlú olódi wọn, ó lérò pé òun óo jagun gbà wọ́n.

2. Nígbà tí Hesekaya rí i pé Senakeribu ti pinnu láti gbógun ti Jerusalẹmu,

3. ó jíròrò pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bí wọn yóo ti ṣe dí ìṣàn omi tí ó wà lẹ́yìn odi ìlú; wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

4. Wọ́n kó ọpọlọpọ eniyan jọ, wọ́n dí àwọn orísun omi ati àwọn odò tí ń ṣàn ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ní, “Kò yẹ kí ọba Asiria wá, kí ó bá omi tí ó tó báyìí.”

5. Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata.

6. Ọba yan àwọn ọ̀gágun lórí àwọn eniyan, ó sì pe gbogbo wọn jọ sí gbàgede ẹnubodè ìlú. Ó dá wọn lọ́kàn le, ó ní,

7. “Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ.

8. Agbára ti ẹran ara ni àwọn ọmọ ogun tirẹ̀ ní, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun ni ó wà pẹlu wa láti ràn wá lọ́wọ́ ati láti jà fún wa.” Ọ̀rọ̀ tí Hesekaya ọba Juda sọ sì fi àwọn eniyan rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀.

9. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Senakeribu ati àwọn ogun rẹ̀ gbógun ti Lakiṣi, ó ranṣẹ sí Hesekaya ọba Juda ati àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pé,

10. “Òun Senakeribu, ọba Asiria ní, kí ni wọ́n gbójú lé tí wọ́n fi dúró sí Jerusalẹmu, ìlú tí ogun dó tì?

11. Ó ní bí Hesekaya bá ní OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun ọba Asiria, ó ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, ó fẹ́ kí òùngbẹ ati ebi pa wọ́n kú ni.

12. Ó ní, Ṣebí Hesekaya yìí kan náà ni ó kó gbogbo oriṣa kúrò ní Jerusalẹmu ati ní Juda tí ó sọ fún wọn pé ibi pẹpẹ kan ṣoṣo ni wọ́n ti gbọdọ̀ máa jọ́sìn, kí wọn sì máa rúbọ níbẹ̀?

13. Ó ní ǹjẹ́ wọ́n mọ ohun tí òun ati baba òun ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn? Ati pé, ǹjẹ́ àwọn oriṣa àwọn orílẹ̀-èdè náà gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria?

14. Ó ní èwo ni oriṣa wọn gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ òun, ninu gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi tí baba òun parun, tí Ọlọrun tiyín yóo fi wá gbà yín?

15. Ó ní nítorí náà, kí wọn má ṣe jẹ́ kí Hesekaya tàn wọ́n jẹ, tabi kí ó ṣì wọ́n lọ́nà báyìí. Ó ní kí wọn má gbọ́ ohun tí ó ń sọ rárá, nítorí pé kò sí oriṣa orílẹ̀-èdè kan tí ó tó gba àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́ òun tabi lọ́wọ́ àwọn baba òun, kí á má wá sọ pé Ọlọrun tiwọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun.”

16. Àwọn iranṣẹ ọba Asiria tún sọ ọ̀rọ̀ burúkú sí OLUWA Ọlọrun ati sí Hesekaya, iranṣẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 32