Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 3:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé náà ní ọjọ́ keji oṣù keji ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.

3. Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọrun tí Solomoni fi lélẹ̀ gùn ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9).

4. Yàrá kan wà ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní ọgọfa igbọnwọ (mita 54), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ déédé ìbú tẹmpili.

5. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bo gbogbo inú rẹ̀. Ó fi igi sipirẹsi tẹ́ gbogbo inú gbọ̀ngàn rẹ̀. Ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó lórí, ó ya igi ọ̀pẹ ati ẹ̀wọ̀n, ó fi dárà sórí rẹ̀.

6. Ó fi òkúta olówó iyebíye ṣe iṣẹ́ ọnà sára ilé náà, wúrà tí ó rà wá láti ilẹ̀ Pafaimu ni ó lò.

7. Ó yọ́ wúrà bo gbogbo igi àjà ilé náà patapata, ati àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ògiri rẹ̀ ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fi àwòrán àwọn kerubu dárà sí ara àwọn ògiri.

8. Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé ìbú tẹmpili náà, ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9). Ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó yọ́ ìwọ̀n ẹgbẹta (600) talẹnti ojúlówó wúrà, ó fi bo gbogbo inú rẹ̀.

9. Aadọta ìwọ̀n ṣekeli wúrà ni ó fi ṣe ìṣó, ó sì yọ́ wúrà bo gbogbo ara ògiri yàrá òkè.

Ka pipe ipin Kronika Keji 3