Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 27:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ó bá ọba àwọn ará Amoni jà, ó sì ṣẹgun wọn. Ní ọdún tí ó ṣẹgun wọn, wọ́n fún un ní ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori alikama ati ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori ọkà baali. Iye kan náà ni wọ́n fún un ní ọdún keji ati ọdún kẹta.

6. Jotamu di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ati àwọn ogun tí ó jà, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó tún ṣe ni a kọ sinu ìwé àwọn ọba Israẹli ati ti Juda.

8. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu.

9. Nígbà tí Jotamu kú, wọ́n sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 27