Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 26:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.

6. Ó gbógun ti àwọn ará Filistia, ó sì wó odi Gati, ati ti Jabine ati ti Aṣidodu lulẹ̀. Ó kọ́ àwọn ìlú olódi ní agbègbè Aṣidodu ati ní ibòmíràn ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia.

7. Ọlọrun ràn án lọ́wọ́, ó ṣẹgun àwọn ará Filistia ati àwọn ará Arabia tí wọ́n ń gbé Guribaali ati àwọn ará Meuni.

8. Àwọn ará Amoni ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún Usaya, òkìkí rẹ̀ kàn káàkiri títí dé agbègbè ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé ó di alágbára gan-an.

9. Usaya tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi Ẹnubodè tí ó wà ní igun odi, ati sí ibi Ẹnubodè àfonífojì, ati níbi Ìṣẹ́po Odi. Ó sì mọ odi sí wọn.

10. Ó tún kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ sinu aṣálẹ̀, ó gbẹ́ ọpọlọpọ kànga, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ agbo ẹran ọ̀sìn ní àwọn ẹsẹ̀ òkè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ń dá oko fún un ati àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu àjàrà, lórí òkè ati lórí àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀.

11. Usaya ní ọpọlọpọ ọmọ ogun, tí wọ́n tó ogun lọ, ó pín wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí ètò tí Jeieli akọ̀wé, ati Maaseaya, ọ̀gágun ṣe, lábẹ́ àkóso Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun ọba.

12. Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé, tí wọ́n sì jẹ́ akọni ọkunrin jẹ́ ẹgbẹtala (2,600).

13. Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lábẹ́ wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹẹdogun ó lé ẹẹdẹgbaarin ati ẹẹdẹgbaata (307,500), wọ́n lágbára láti jagun, ati láti bá ọba dojú kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀.

14. Usaya ọba fún gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní apata, ọ̀kọ̀, àṣíborí, ẹ̀wù ihamọra, ọfà, ati òkúta fún kànnàkànnà wọn.

15. Ó ní àwọn ẹ̀rọ tí àwọn alágbẹ̀dẹ ṣe sórí àwọn ilé ìṣọ́ ati àwọn igun odi ní Jerusalẹmu láti máa tafà ati láti máa sọ àwọn òkúta ńláńlá. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri nítorí pé Ọlọrun ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nà ìyanu títí ó fi di alágbára.

16. Ṣugbọn nígbà tí Usaya di alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ tì í ṣubú. Ó ṣe aiṣootọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó wọ inú tẹmpili OLUWA, ó lọ sun turari lórí pẹpẹ turari.

17. Ṣugbọn Asaraya, alufaa, wọlé lọ bá a pẹlu àwọn ọgọrin alufaa tí wọ́n jẹ́ akọni.

Ka pipe ipin Kronika Keji 26