Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 24:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ ọdún meje ni Joaṣi nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibaya, ará Beeriṣeba.

2. Joaṣi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Jehoiada alufaa.

3. Jehoiada fẹ́ iyawo meji fún un, wọ́n sì bímọ fún un lọkunrin ati lobinrin.

4. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Joaṣi pinnu láti tún ilé OLUWA ṣe.

5. Ó pe gbogbo àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ máa gba owó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti máa fi tún ilé OLUWA Ọlọrun yín ṣe ní ọdọọdún. Ẹ mójútó iṣẹ́ náà kí ẹ sì ṣe é kíákíá.” Ṣugbọn àwọn alufaa kò tètè lọ.

6. Nítorí náà, ọba ranṣẹ pe Jehoiada tí ó jẹ́ olórí wọn, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Lefi lọ máa gba owó fún àgọ́ ẹ̀rí lọ́wọ́ àwọn eniyan Juda ati Jerusalẹmu bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pa á láṣẹ?”

7. (Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Atalaya, obinrin burúkú n nì, ti fọ́ ilé Ọlọrun, wọ́n sì ti kó gbogbo ohun èlò mímọ́ ibẹ̀, wọ́n ti lò ó fún oriṣa Baali.)

8. Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àpótí kan tí àwọn eniyan yóo máa sọ owó sí, kí wọ́n sì gbé e sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Kronika Keji 24