Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 23:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Jehoiada yan àwọn aṣọ́nà fún ilé OLUWA, lábẹ́ àkóso àwọn alufaa, ọmọ Lefi, ati àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi ti ṣètò láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, pẹlu àjọyọ̀ ati orin, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣètò.

19. Ó fi àwọn aṣọ́nà sí ẹnu àwọn ọ̀nà ilé OLUWA kí ẹnikẹ́ni tí kò bá mọ́ má baà wọlé.

20. Òun pẹlu àwọn balogun, àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn, àwọn gomina, ati gbogbo eniyan ilẹ̀ náà mú ọba láti ilé OLUWA, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà òkè wá sí ààfin, wọ́n sì fi í jókòó lórí ìtẹ́.

21. Inú gbogbo àwọn eniyan dùn, ìlú sì rọ̀ wọ̀ọ̀, nítorí pé wọ́n ti pa Atalaya.

Ka pipe ipin Kronika Keji 23