Àwọn ọmọ ogun Arabia tí wọn ń jà káàkiri pa gbogbo àwọn ọmọ Jehoramu, ọba Juda, àfi Ahasaya, àbíkẹ́yìn rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Jerusalẹmu bá fi Ahasaya jọba lẹ́yìn Jehoramu.