orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 22 BIBELI MIMỌ (BM)

Ahasaya Ọba Juda

1. Àwọn ọmọ ogun Arabia tí wọn ń jà káàkiri pa gbogbo àwọn ọmọ Jehoramu, ọba Juda, àfi Ahasaya, àbíkẹ́yìn rẹ̀. Nítorí náà àwọn ará Jerusalẹmu bá fi Ahasaya jọba lẹ́yìn Jehoramu.

2. Ahasaya jẹ́ ẹni ọdún mejilelogoji, nígbà tí ó jọba; ó sì wà lórí oyè fún ọdún kan ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Atalaya, ọmọ ọmọ Omiri.

3. Ìwà burúkú ni òun náà ń hù bíi ti Ahabu, nítorí pé ìyá rẹ̀ ní ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà ibi.

4. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, àwọn ará ilé Ahabu ni olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ni wọ́n fa ìṣubú rẹ̀.

5. Ìmọ̀ràn wọn ni ó tẹ̀lé tí ó fi pa ogun tirẹ̀ pọ̀ mọ́ ti Joramu, ọba Israẹli, láti bá Hasaeli ọba Siria jagun ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Siria sì ṣá Joramu lọ́gbẹ́ lójú ogun náà,

6. ó bá pada lọ sí ìlú Jesireeli láti wo ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun ní Rama nígbà tí ó ń bá Hasaeli ọba Siria jagun. Ahasaya, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli nítorí ara rẹ̀ tí kò yá.

7. Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run.

8. Nígbà tí Jehu dé láti pa ilé Ahabu run bí Ọlọrun ti fún un láṣẹ, ó pàdé àwọn ìjòyè Juda ati ọmọ arakunrin Ahasaya tí ó bá Ahasaya wá, ó bá pa wọ́n.

9. Ó wá Ahasaya káàkiri títí; ní Samaria níbi tí ó sá pamọ́ sí ni wọ́n ti rí i mú, wọ́n bá mú un tọ Jehu wá, ó sì pa á. Wọ́n sin òkú rẹ̀, nítorí wọ́n ní, “Ọmọ ọmọ Jehoṣafati, ẹni tí ó fi tọkàntọkàn gbọ́ ti OLUWA ni.”Ní àkókò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni ninu ìdílé Ahasaya tí ó lágbára tó láti jọba ilẹ̀ Juda.

Atalaya, Ọbabinrin ní Juda

10. Nígbà tí Atalaya, ìyá Ahasaya rí i pé ọmọ òun ti kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìran ọba ní Juda.

11. Ṣugbọn Jehoṣeba, ọmọbinrin Jehoramu ọba, tí ó jẹ́ iyawo Jehoiada alufaa, gbé Joaṣi ọmọ Ahasaya sá kúrò láàrin àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, nítorí pé àbúrò rẹ̀ ni Joaṣi yìí. Ó bá fi òun ati olùtọ́jú rẹ̀ pamọ́ sinu yàrá kan. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣeba ṣe gbé ọmọ náà pamọ́ fún Atalaya, tí kò fi rí i pa.

12. Joaṣi wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n gbé e pamọ́ sí ninu ilé OLUWA fún ọdún mẹfa tí Atalaya fi jọba ní ilẹ̀ náà.