Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 20:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun.

2. Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi).

3. Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀.

4. Àwọn eniyan péjọ láti gbogbo ìlú Juda, wọ́n wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ OLUWA.

5. Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun,

6. ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́.

7. Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae?

8. Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,

9. nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá.

Ka pipe ipin Kronika Keji 20