Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 2:9-12 BIBELI MIMỌ (BM)

9. láti tọ́jú ọpọlọpọ igi, nítorí pé ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi, yóo sì jọjú.

10. N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.”

11. Huramu, ọba Tire, bá dá èsì lẹta Solomoni pada, ó ní, “OLUWA fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn.”

12. Ó tún fi kún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó dá ọ̀run ati ayé, tí ó fún Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó sì ní òye ati ìmọ̀ láti kọ́ tẹmpili fún OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 2