Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 18:31-34 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati, wọ́n rò pé ọba Israẹli ni, wọ́n bá yíjú sí i láti bá a jà. Jehoṣafati bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, OLUWA sì gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.

32. Nígbà tí àwọn ọ̀gágun náà rí i pé kì í ṣe Ahabu, ọba Israẹli, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀.

33. Ṣugbọn ọmọ ogun Siria kan déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí ìgbàyà ati ihamọra rẹ̀ ti pàdé. Ó bá kígbe sí ẹni tí ó ru ihamọra rẹ̀ pé, “Mo ti fara gbọgbẹ́, yipada kí o gbé mi kúrò lójú ogun.”

34. Ogun gbóná ní ọjọ́ náà, Ahabu ọba bá rá pálá dìde dúró, wọ́n fi ọwọ́ mú un ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó kọjú sí ogun Siria. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, ó kú.

Ka pipe ipin Kronika Keji 18