Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 14:12-15 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá.

13. Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun.

14. Wọ́n run gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè Gerari, nítorí pé ẹ̀rù OLUWA ba àwọn ará ibẹ̀. Wọ́n fi ogun kó gbogbo àwọn ìlú náà nítorí pé ìkógun pọ̀ ninu wọn.

15. Wọ́n wó gbogbo àgọ́ àwọn tí ń sin mààlúù, wọ́n sì kó ọpọlọpọ aguntan ati ràkúnmí wọn pada sí Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Kronika Keji 14