Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 13:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun.

15. Àwọn ọmọ ogun Juda hó ìhó ogun, bí wọ́n sì ti kígbe ni Ọlọrun ṣẹgun Jeroboamu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli fún Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda.

16. Àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, Ọlọrun sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ ogun Juda lọ́wọ́.

17. Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda pa àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ìpakúpa, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000) fi kú ninu àwọn akọni ọmọ ogun Israẹli.

18. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda ṣe tẹ orí àwọn ọmọ Israẹli ba tí wọ́n sì ṣẹgun wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Juda gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.

19. Abija lé Jeroboamu, ó sì gba ìlú Bẹtẹli, ati Jeṣana, ati Efuroni ati àwọn ìletò tí ó yí wọn ká lọ́wọ́ rẹ̀.

20. Jeroboamu kò sì lè gbérí ní àkókò Abija. Nígbà tí ó yá Ọlọrun lu Jeroboamu pa.

21. Ṣugbọn agbára Abija bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ síi. Iyawo mẹrinla ni ó ní; ó sì bí ọmọkunrin mejilelogun ati ọmọbinrin mẹrindinlogun.

22. Gbogbo nǹkan yòókù ti Abija ṣe ní àkókò ìjọba rẹ̀, ati ohun tí ó sọ, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn wolii Ido.

Ka pipe ipin Kronika Keji 13