Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 13:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Jeroboamu ni Abija jọba ní ilẹ̀ Juda.

2. Ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikaya, ọmọ Urieli ará Gibea.Nígbà kan, ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin Abija ati Jeroboamu.

3. Abija kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) akọni ọmọ ogun jọ láti bá Jeroboamu jagun. Jeroboamu náà kó ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) akọni ọmọ ogun jọ.

4. Abija gun orí òkè Semaraimu tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu lọ. Ó kígbe lóhùn rara, ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Jeroboamu ati gbogbo ẹ̀yin eniyan Israẹli,

5. ṣé ẹ ẹ̀ mọ̀ pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fi iyọ̀ bá Dafidi dá majẹmu ayérayé pé àtìrandíran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli títí lae?

6. Sibẹsibẹ, Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi, dìde, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Solomoni, oluwa rẹ̀.

7. Ó sì lọ kó àwọn jàǹdùkú ati àwọn aláìníláárí eniyan kan jọ, wọ́n pe Rehoboamu ọmọ Solomoni níjà. Rehoboamu jẹ́ ọmọde nígbà náà, kò sì ní ìrírí tó láti dojú ìjà kọ wọ́n.

8. Nisinsinyii, ẹ rò pé ẹ lè dojú ìjà kọ ìjọba OLUWA, tí ó gbé lé àwọn ọmọ Dafidi lọ́wọ́; nítorí pé ẹ pọ̀ ní iye ati pé ẹ ní ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí Jeroboamu fi wúrà ṣe tí ó pè ní ọlọrun yín?

9. Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun.

Ka pipe ipin Kronika Keji 13