18. Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọ Jerimotu, ọmọ Dafidi, ìyá rẹ̀ ni Abihaili, ọmọ Eliabu, ọmọ Jese.
19. Iyawo Rehoboamu yìí bí ọmọkunrin mẹta fún un; wọ́n ń jẹ́: Jeuṣi, Ṣemaraya ati Sahamu.
20. Lẹ́yìn náà, ó tún fẹ́ Maaka, ọmọ Absalomu; òun bí ọmọkunrin mẹrin fún un; wọ́n ń jẹ́ Abija, Atai, Sisa ati Ṣelomiti.
21. Maaka, ọmọ Absalomu ni Rehoboamu fẹ́ràn jùlọ ninu àwọn iyawo rẹ̀. Àwọn mejidinlogun ni ó gbé ní iyawo, o sì ní ọgọta obinrin mìíràn. Ó bí ọmọkunrin mejidinlọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin.
22. Ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tí ń jẹ́ Abija ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ. Ó yàn án láti jẹ́ ọba lẹ́yìn tí òun bá kú.
23. Ó dọ́gbọ́n fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe olórí káàkiri, ó pín wọn káàkiri jákèjádò ilẹ̀ Juda ati Bẹnjamini ní àwọn ìlú alágbára. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n ṣe aláìní. Ó sì fẹ́ iyawo fún gbogbo wọn.