Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 10:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn tèmi yóo tún wúwo ju ti baba mi lọ. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi ta yín.’ ”

12. Ní ọjọ́ kẹta, Jeroboamu pẹlu àwọn ọmọ Israẹli bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn.

13. Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn,

14. ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.”

15. Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ.

Ka pipe ipin Kronika Keji 10