Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 1:13-17 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Solomoni kúrò ní àgọ́ ìpàdé tí ó wà ní ibi ìrúbọ ní Gibeoni, ó wá sí Jerusalẹmu, ó sì jọba lórí Israẹli.

14. Solomoni kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin jọ; àwọn kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ egbeje (1,400) àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ ẹgbaafa (12,000); ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

15. Fadaka ati wúrà tí ọba kójọ, pọ̀ bíi òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bí igi sikamore tí ó wà ní Ṣefela, ní ẹsẹ̀ òkè Juda.

16. Láti Ijipti ati Kue ni Solomoni ti ń kó ẹṣin wá, àwọn oníṣòwò tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún un ni wọ́n ń ra àwọn ẹṣin náà wá láti Kue.

17. Àwọn oníṣòwò a máa ra kẹ̀kẹ́ ogun kan ni ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka wá fún Solomoni láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn náà ni wọ́n sì ń bá a tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati ti ilẹ̀ Siria.

Ka pipe ipin Kronika Keji 1