Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 9:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti bá àwọn eniyan náà ṣe àdéhùn, ni wọ́n gbọ́ pé nítòsí wọn ni wọ́n wà, ati pé aládùúgbò ni wọ́n.

17. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú wọn. Àwọn ìlú náà ni: Gibeoni, Kefira, Beeroti ati Kiriati Jearimu.

18. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò pa wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà wọn ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Gbogbo ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí i kùn sí àwọn àgbààgbà.

19. Ṣugbọn gbogbo àwọn àgbààgbà dá ìjọ eniyan náà lóhùn pé, “A ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli, a kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kàn wọ́n mọ́.

20. Ohun tí a lè ṣe ni pé kí á dá wọn sí, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a ti ṣe fún wọn.”

21. Àwọn àgbààgbà bá wí fún wọn pé, “Ẹ má pa wọ́n.” Àwọn àgbààgbà Israẹli bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà di aṣẹ́gi ati apọnmi fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

22. Joṣua pè wọ́n, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi tàn wá jẹ, tí ẹ wí fún wa pé, ọ̀nà jíjìn ni ẹ ti wá, nígbà tí ó jẹ́ pé ààrin wa níbí ni ẹ̀ ń gbé?

23. Nítorí náà, ẹ di ẹni ìfibú; ẹrú ni ẹ óo máa ṣe, ẹ̀yin ni ẹ óo máa ṣẹ́ igi tí ẹ óo sì máa pọnmi fun ilé Ọlọrun mi.”

24. Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe.

25. Sibẹsibẹ, ọwọ́ yín náà ni a ṣì wà; ẹ ṣe wá bí ó bá ti tọ́ lójú yín.”

26. Ohun tí Joṣua ṣe fún wọn ni pé ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n.

27. Ṣugbọn láti ọjọ́ náà ni Joṣua ti sọ wọ́n di ẹni tí ó ń ṣẹ́ igi, tí ó sì ń pọn omi fún àwọn eniyan Israẹli, ati fún pẹpẹ OLUWA. Títí di òní, àwọn ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà ní ibi tí OLUWA yàn pé kí àwọn ọmọ Israẹli ti máa jọ́sìn.

Ka pipe ipin Joṣua 9