Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 5:9-11 BIBELI MIMỌ (BM)

9. OLUWA wí fún Joṣua pé, “Lónìí yìí ni mo mú ẹ̀gàn àwọn ará Ijipti kúrò lára yín.” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Giligali títí di òní olónìí.

10. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí Giligali, wọ́n ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù náà, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.

11. Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ.

Ka pipe ipin Joṣua 5