Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 5:12-15 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà.

13. Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?”

14. Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.”Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?”

15. Balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA dá Joṣua lóhùn pé, “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Joṣua 5