Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 24:2-11 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà.

3. Láti òdìkejì odò náà ni mo ti mú Abrahamu baba yín, mo sìn ín la gbogbo ilẹ̀ Kenaani já; mo sì sọ arọmọdọmọ rẹ̀ di pupọ. Mo fún un ní Isaaki;

4. mo sì fún Isaaki ni Jakọbu ati Esau. Mo fún Esau ní òkè Seiri bí ohun ìní tirẹ̀, ṣugbọn Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti.

5. Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde.

6. Mo kó àwọn baba yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ẹ dé etí òkun, àwọn ará Ijipti kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì lé àwọn baba yín títí dé etí Òkun Pupa.

7. Nígbà tí àwọn baba yín ké pe OLUWA, OLUWA fi òkùnkùn sí ààrin ẹ̀yin ati àwọn ará Ijipti, ó sì mú kí òkun bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin náà ṣá fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ijipti.“ ‘Ẹ wà ninu aṣálẹ̀ fún ìgbà pípẹ́,

8. lẹ́yìn náà mo ko yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani. Wọ́n ba yín jà, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ẹ gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n run lójú yín.

9. Lẹ́yìn náà, Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu, dìde láti bá Israẹli jagun, ó ranṣẹ sí Balaamu, ọmọ Beori, láti wá fi yín gégùn-ún.

10. Ṣugbọn n kò fetísí ọ̀rọ̀ Balaamu; nítorí náà ìre ni ó sú fun yín, mo sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.

11. Ẹ gun òkè odò Jọdani wá sí Jẹriko, àwọn ará Jẹriko sì gbógun tì yín, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Joṣua 24