Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 24:16-28 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà náà ni àwọn eniyan náà dáhùn, wọ́n ní, “Kí á má rí i pé a kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń bọ oriṣa.

17. Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun wa ni ó kó àwa ati àwọn baba wa jáde ní oko ẹrú ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀n-ọn-nì lójú wa. Òun ni ó dá ẹ̀mí wa sí ní gbogbo ọ̀nà tí a tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a là kọjá.

18. OLUWA sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà kúrò níwájú wa ati àwọn ará Amori tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀. Nítorí náà OLUWA ni a óo máa sìn nítorí pé òun ni Ọlọrun wa.”

19. Ṣugbọn Joṣua dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ kò lè sin OLUWA, nítorí pé Ọlọrun mímọ́ ni, Ọlọrun owú sì ni pẹlu, kò sì ní dárí àwọn àìṣedéédé ati ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

20. Lẹ́yìn tí OLUWA bá ti ṣe yín lóore, bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa àjèjì, yóo yipada láti ṣe yín níbi, yóo sì pa yín run.”

21. Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “Rárá o, OLUWA ni a óo máa sìn.”

22. Joṣua bá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín, pé OLUWA ni ẹ yàn láti máa sìn.”Wọ́n dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”

23. Lẹ́yìn náà, Joṣua sọ fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kó àwọn oriṣa àjèjì tí ó wà láàrin yín dànù, kí ẹ sì fi ọkàn sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli.”

24. Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun wa ni a óo máa sìn, tirẹ̀ ni a óo sì máa gbọ́.”

25. Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.

26. Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA,

27. ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.”

28. Joṣua bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà máa lọ, kí olukuluku pada sí orí ilẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Joṣua 24