Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 24:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA.

2. Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà.

3. Láti òdìkejì odò náà ni mo ti mú Abrahamu baba yín, mo sìn ín la gbogbo ilẹ̀ Kenaani já; mo sì sọ arọmọdọmọ rẹ̀ di pupọ. Mo fún un ní Isaaki;

4. mo sì fún Isaaki ni Jakọbu ati Esau. Mo fún Esau ní òkè Seiri bí ohun ìní tirẹ̀, ṣugbọn Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti.

5. Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde.

Ka pipe ipin Joṣua 24