Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 23:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí pé, OLUWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì ní agbára kúrò níwájú yín, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè ṣẹgun yín títí di òní.

10. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ninu yín ni ó ń bá ẹgbẹrun eniyan jà, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín.

11. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín.

12. Nítorí pé, bí ẹ bá yipada, tí ẹ sì darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, tí ẹ̀ ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, tí àwọn náà sì ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ yín,

13. ẹ mọ̀ dájú pé, OLUWA Ọlọrun yín kò ní lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde kúrò fun yín mọ́; ṣugbọn wọn óo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fun yín, OLUWA yóo sì fi wọ́n ṣe pàṣán tí yóo máa fi nà yín. Wọn óo dàbí ẹ̀gún, wọn óo máa gún yín lójú, títí tí ẹ óo fi parun patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

Ka pipe ipin Joṣua 23