Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 23:3-10 BIBELI MIMỌ (BM)

3. ẹ̀yin náà ti rí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nítorí yín, ati pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó jà fun yín.

4. Ẹ wò ó! Gbogbo ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí a kò tíì ṣẹgun, ati gbogbo àwọn tí a ti ṣẹgun ni mo ti pín fun yín gẹ́gẹ́ bí ogún yín, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn,

5. OLUWA Ọlọrun yín yóo máa tì wọ́n sẹ́yìn fun yín, yóo máa lé wọn kúrò níwájú yín, ẹ óo sì gba ilẹ̀ wọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti ṣèlérí fun yín.

6. Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì,

7. kí ẹ má baà darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, kí ẹ má baà máa bọ àwọn oriṣa wọn, tabi kí ẹ máa fi orúkọ wọn búra, tabi kí ẹ máa sìn wọ́n, tabi kí ẹ máa foríbalẹ̀ fún wọn.

8. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ súnmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe títí di òní.

9. Nítorí pé, OLUWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì ní agbára kúrò níwájú yín, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè ṣẹgun yín títí di òní.

10. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ninu yín ni ó ń bá ẹgbẹrun eniyan jà, nítorí pé OLUWA Ọlọrun yín ni ó ń jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín.

Ka pipe ipin Joṣua 23